Native Bible

Philippians 1:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe àmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là.

Philippians 1:28 in English

Philippians 1:28 · Berean Standard Bible

without being frightened in any way by those who oppose you. This is a clear sign of their destruction but of your salvation, and it is from God.

Context

26kí ìṣògo yín kí ó lè di púpọ̀ gidigidi nínú Jesu Kristi, àti nínú mi nípa ìpadà wá mi sọ́dọ̀ yín. 27Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìyìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan. 28Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe àmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là. 29Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú. 30Ẹ sì máa ja ìjà kan náà, èyí ti ẹ̀yin ti ri, ti ẹ sì ti gbọ́ pé èmi n jà pẹ̀lú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.