Filemoni 1:17
Philemon 1:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí.
Philemon 1:17 in English
Philemon 1:17 · Berean Standard Bible
So if you consider me a partner, receive him as you would receive me.
Context
15Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé. 16Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa. 17Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí. 18Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbèsè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn. 19Èmi Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ ní í sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbèsè ara rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.