Native Bible

Numbers 9:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nípa àṣẹ Olúwa ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

Numbers 9:23 in English

Numbers 9:23 · Berean Standard Bible

They camped at the LORD’s command, and they set out at the LORD’s command; they carried out the LORD’s charge according to His command through Moses.

Context

21Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè dúró láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀, nígbà tó bá ṣí kúrò ní àárọ̀, wọn ó gbéra. Ìbá à ṣe ní ọ̀sán tàbí òru, ìgbàkígbà tí ìkùùkuu bá tó kúrò náà ni wọn ó tó gbéra. 22Ìbá à ṣe fún ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí ọdún kan ni ìkùùkuu fi dúró sórí àgọ́, àwọn ọmọ Israẹli yóò dúró ní ibùdó wọn, wọn kò ní gbéra; ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá lọ sókè ni wọn ó tó o gbéra. 23Nípa àṣẹ Olúwa ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.