Native Bible

Numbers 8:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mú kí àwọn ọmọ Lefi dúró níwájú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì sí Olúwa.

Numbers 8:13 in English

Numbers 8:13 · Berean Standard Bible

You are to have the Levites stand before Aaron and his sons and then present them before the LORD as a wave offering.

Context

11Aaroni yóò sì mú àwọn ọmọ Lefi wá síwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli wá, kí wọn lè máa ṣiṣẹ́ Olúwa. 12“Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi bá gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ ọmọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun sí Olúwa, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Lefi. 13Mú kí àwọn ọmọ Lefi dúró níwájú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì sí Olúwa. 14Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Lefi sọ́tọ̀, kúrò láàrín àwọn ọmọ Israẹli yòókù, àwọn ọmọ Lefi yóò sì jẹ́ tèmi. 15“Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.