Native Bible

Numbers 7:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai, olórí àwọn ọmọ Simeoni ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ karùn-ún.

Numbers 7:36 in English

Numbers 7:36 · Berean Standard Bible

On the fifth day Shelumiel son of Zurishaddai, the leader of the Simeonites, drew near.

Context

34akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; 35màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Elisuri ọmọ Ṣedeuri. 36Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai, olórí àwọn ọmọ Simeoni ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ karùn-ún. 37Ọrẹ tí ó kó wá ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; 38àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.