Native Bible

Numbers 7:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Eliabu ọmọ Heloni, olórí àwọn ọmọ Sebuluni ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹta.

Numbers 7:24 in English

Numbers 7:24 · Berean Standard Bible

On the third day Eliab son of Helon, the leader of the Zebulunites, drew near.

Context

22akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; 23Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Netaneli ọmọ Suari. 24Eliabu ọmọ Heloni, olórí àwọn ọmọ Sebuluni ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹta. 25Àwọn ọrẹ rẹ̀ ni: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ; 26àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.