Numeri 5:27
Numbers 5:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
Numbers 5:27 in English
Numbers 5:27 · Berean Standard Bible
When he has made her drink the water, if she has defiled herself and been unfaithful to her husband, then the water that brings a curse will enter her and cause bitter suffering; her belly will swell, her thigh will shrivel, and she will become accursed among her people.
Context
25Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ owú náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í síwájú Olúwa, yóò sì mú iná sórí pẹpẹ. 26Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ọrẹ ohun jíjẹ náà, yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lẹ́yìn tí ó ti mú kí obìnrin náà mu omi. 27Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì ṣe àìṣòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 28Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé obìnrin náà kò ba ara rẹ̀ jẹ́, tó sì jẹ́ mímọ́, yóò bọ́ nínú ẹ̀bi, yóò sì le bímọ. 29“ ‘Èyí ni òfin owú jíjẹ nígbà tí obìnrin tó wà lábẹ́ ọkọ bá ṣe a ṣe má ṣe, tí ó bá ba ara rẹ̀ jẹ́,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.