Numeri 5:18
Numbers 5:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì tú irun orí obìnrin náà lé e lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnra rẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́.
Numbers 5:18 in English
Numbers 5:18 · Berean Standard Bible
After the priest has the woman stand before the LORD, he is to let down her hair and place in her hands the grain offering of memorial, which is the grain offering for jealousy. The priest is to hold the bitter water that brings a curse.
Context
16“ ‘Àlùfáà yóò sì mú un wá síwájú Olúwa. 17Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀. 18Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú Olúwa yóò sì tú irun orí obìnrin náà lé e lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnra rẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́. 19Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní ṣe ọ́ níbi. 20Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá ti yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ, tí o bá ti ba ara rẹ jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ọkùnrin tí kì í ṣe ọkọ rẹ bá ọ lòpọ̀,”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.