Native Bible

Numbers 4:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

Numbers 4:8 in English

Numbers 4:8 · Berean Standard Bible

And they shall spread a scarlet cloth over them, cover them with fine leather, and insert the poles.

Context

6Wọn yóò sì fi awọ ewúrẹ́ bò ó, lórí awọ ewúrẹ́ yìí ni wọn ó tẹ̀ bọ ààyè rẹ̀. 7“Lórí tábìlì àkàrà ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, kí wọn kí ó sì fi àwopọ̀kọ́ sórí rẹ̀, àti ṣíbí àti àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àti àkàrà ìgbà gbogbo ní kí ó wà lórí rẹ̀. 8Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀. 9“Kí wọn kí ó sì mú aṣọ aláwọ̀ aláró kan, kí wọn kí ó sì fi bo ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alumagaji rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. 10Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.