Numeri 4:33
Numbers 4:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Merari, bí wọn yóò ti máa ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà.”
Numbers 4:33 in English
Numbers 4:33 · Berean Standard Bible
This is the service of the Merarite clans according to all their work at the Tent of Meeting, under the direction of Ithamar son of Aaron the priest.”
Context
31Iṣẹ́ tí wọn yóò sì máa ṣe nínú àgọ́ ìpàdé nìyìí: gbígbẹ́ àwọn férémù àgọ́, pákó ìdábùú rẹ̀, òpó àti ihò òpó rẹ̀, 32pẹ̀lú gbogbo òpó tó yí àgbàlá ká àti ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn, kí o sì yan ohun tí oníkálùkù yóò rù fún un. 33Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Merari, bí wọn yóò ti máa ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà.” 34Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn olórí ìjọ ènìyàn ka àwọn ọmọ Kohati nípa ìdílé àti ilé baba wọn. 35Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ ìpàdé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.