Native Bible

Numbers 4:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ka iye àwọn ọmọ Merari nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.

Numbers 4:29 in English

Numbers 4:29 · Berean Standard Bible

As for the sons of Merari, you are to number them by their clans and families,

Context

27Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gerṣoni yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn; ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un. 28Èyí ni iṣẹ́ ìdílé àwọn Gerṣoni ni àgọ́ ìpàdé Itamari, ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni yóò sì jẹ alábojútó iṣẹ́ wọn. 29“Ka iye àwọn ọmọ Merari nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. 30Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 31Iṣẹ́ tí wọn yóò sì máa ṣe nínú àgọ́ ìpàdé nìyìí: gbígbẹ́ àwọn férémù àgọ́, pákó ìdábùú rẹ̀, òpó àti ihò òpó rẹ̀,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.