Native Bible

Numbers 4:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti àgọ́, ti àgọ́ ìpàdé àti ìbòrí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,

Numbers 4:25 in English

Numbers 4:25 · Berean Standard Bible

They are to carry the curtains of the tabernacle, the Tent of Meeting with the covering of fine leather over it, the curtains for the entrance to the Tent of Meeting,

Context

23Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 24“Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àti ní ẹrù rírù. 25Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti àgọ́, ti àgọ́ ìpàdé àti ìbòrí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, 26aṣọ títa ti àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sí àgbàlá, okùn àti àwọn ohun èlò iṣẹ́ ìsìn, àti ohun gbogbo tí à ń lò fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ó máa sìn. Àwọn ọmọ Gerṣoni ni yóò ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí. 27Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gerṣoni yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn; ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.