Native Bible

Numbers 36:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé a gbé Mahila, Tirsa, Hogla, Milka, àti Noa, àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn.

Numbers 36:11 in English

Numbers 36:11 · Berean Standard Bible

Mahlah, Tirzah, Hoglah, Milcah, and Noah, the daughters of Zelophehad, were married to cousins on their father’s side.

Context

9Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Israẹli gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún.” 10Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose. 11Nítorí pé a gbé Mahila, Tirsa, Hogla, Milka, àti Noa, àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn. 12Wọ́n fẹ́ ọkọ nínú ìdílé ìran Manase, ọmọ Josẹfu ogún wọn kù nínú ìdílé àti ẹ̀yà baba wọn. 13Wọ̀nyí ni àṣẹ àti ìdájọ́ tí Olúwa ti ipasẹ̀ Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jordani létí Jeriko.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.