Numeri 35:7
Numbers 35:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi ní méjìdínláàádọ́ta ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.
Numbers 35:7 in English
Numbers 35:7 · Berean Standard Bible
The total number of cities you give the Levites will be forty-eight, with their corresponding pasturelands.
Context
5Lẹ́yìn ìlú náà, wọn ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ lápá ibi ìhà ìlà-oòrùn, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹsẹ̀ bàtà ní ìhà gúúsù, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ní ìhà àríwá, kí ìlú náà sì wà ní àárín. Wọn yóò ní agbègbè yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà. 6“Mẹ́fà lára ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi yóò jẹ́ ìlú ààbò, tí ẹni tí ó bá pa ènìyàn yóò sá sí. Ní àfikún, ẹ fún wọn ní méjìlélógójì ìlú sí i. 7Ní gbogbo rẹ̀, kí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi ní méjìdínláàádọ́ta ìlú lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn. 8Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.” 9Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.