Numeri 35:30
Numbers 35:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn gbọdọ̀ kú gẹ́gẹ́ bí apànìyàn lórí ìjẹ́rìí àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo. Kì yóò jẹ́rìí sí ẹnìkan láti pa.
Numbers 35:30 in English
Numbers 35:30 · Berean Standard Bible
If anyone kills a person, the murderer is to be put to death on the testimony of the witnesses. But no one is to be put to death based on the testimony of a lone witness.
Context
28Ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn gbọdọ̀ dúró nínú ìlú ìsásí títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú; lẹ́yìn ikú olórí àlùfáà, ni ó tó lè padà sí ibi tí dúkìá rẹ̀ wà. 29“ ‘Wọ̀nyí ni ó jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún yín ní ìran yín tó ń bọ̀, ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé. 30“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn gbọdọ̀ kú gẹ́gẹ́ bí apànìyàn lórí ìjẹ́rìí àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo. Kì yóò jẹ́rìí sí ẹnìkan láti pa. 31“ ‘Má ṣe gba ohun ìràpadà fún ẹ̀mí apànìyàn, tí ó jẹ̀bi kí ó kú. Ṣùgbọ́n pípa ni kí a pa á. 32“ ‘Má ṣe gba ìràsílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá lọ sí ìlú ìsásí, pe kí ó padà máa gbé ní ilẹ̀ tirẹ̀ kí ó tó di ìgbà ikú olórí àlùfáà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.