Native Bible

Numbers 35:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Israẹli, fún àjèjì àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrín wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sálọ síbẹ̀.

Numbers 35:15 in English

Numbers 35:15 · Berean Standard Bible

These six cities will serve as a refuge for the Israelites and for the foreigner or stranger among them, so that anyone who kills a person unintentionally may flee there.

Context

13Mẹ́fà nínú ìlú tí ẹ ó fi fún wọn yóò jẹ́ ìlú ààbò fún yín. 14Yan ìlú mẹ́ta ní ìhà ti Jordani, kí ẹ sì yan ìlú mẹ́ta ní ìhà Kenaani tí yóò máa jẹ́ ìlú ìsásí. 15Ìlú mẹ́fà yìí yóò jẹ́ ìlú ìsásí fún àwọn ọmọ Israẹli, fún àjèjì àti ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé láàrín wọn, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ sálọ síbẹ̀. 16“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fi ohun èlò irin lu ènìyàn tí ó kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa, apànìyàn náà. 17Tàbí tí ènìyàn bá mú òkúta tí ó lè pa ènìyàn lọ́wọ́ tí ó sì fi lu ènìyàn, tí ó sì kú, apànìyàn ni, pípa ni a ó pa apànìyàn náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.