Numeri 35:10
Numbers 35:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jordani sí Kenaani,
Numbers 35:10 in English
Numbers 35:10 · Berean Standard Bible
“Speak to the Israelites and tell them: When you cross the Jordan into the land of Canaan,
Context
8Ìlú tí ẹ fún àwọn ọmọ Lefi láti ara ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli jogún, olúkúlùkù kí ó fi nínú ìlú rẹ̀ fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní rẹ̀ tí ó ní. Gba púpọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní púpọ̀ àti díẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yà tí ó ní díẹ̀.” 9Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, 10“Sọ̀rọ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí ẹ bá rékọjá odò Jordani sí Kenaani, 11yan àwọn ìlú kan láti jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlú ààbò fún yín, kí apani tó pa ènìyàn ní àìmọ̀ máa sálọ síbẹ̀. 12Wọn yóò jẹ́ ibi ìsásí kúrò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san, kí ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn má ba à kú kí ó tó dúró níwájú àwọn ìjọ àwọn ènìyàn ní ìdájọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.