Native Bible

Numbers 33:55 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lé àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, àwọn tí ẹ bá jẹ́ kí ó kù yóò di ọfà nínú ojú yín, àti ẹ̀gún ní ìhà yín. Wọn yóò fún yín ní wàhálà ní ilẹ̀ náà tí ẹ̀yin yóò gbé.

Numbers 33:55 in English

Numbers 33:55 · Berean Standard Bible

But if you do not drive out the inhabitants of the land before you, those you allow to remain will become barbs in your eyes and thorns in your sides; they will harass you in the land where you settle.

Context

53Ẹ gba ilẹ̀ náà, kí ẹ̀yin sì máa gbé inú rẹ̀, nítorí èmi ti fi ilẹ̀ náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín. 54Ẹ̀yin pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú kèké, gẹ́gẹ́ bí ìdílé yín. Fún ọ̀pọ̀ ni kí ẹ̀yin ó fi ilẹ̀ ìní púpọ̀ fún, àti fún díẹ̀, ni kí ẹ̀yin kí ó fi ilẹ̀ ìní díẹ̀ fún. Ohunkóhun tí ó bá bọ́ sí ọ̀dọ̀ wọn nípa kèké yóò jẹ́ tiwọn. Pín wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìran wọn. 55“ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lé àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, àwọn tí ẹ bá jẹ́ kí ó kù yóò di ọfà nínú ojú yín, àti ẹ̀gún ní ìhà yín. Wọn yóò fún yín ní wàhálà ní ilẹ̀ náà tí ẹ̀yin yóò gbé. 56Nígbà náà, èmi yóò ṣe sí yín, ohun tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.