Native Bible

Numbers 32:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kọ̀ láti ṣe èyí, ẹ̀yin yóò máa dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa; kí ẹ̀yin kí ó sì mọ̀ dájú pé ẹ̀ṣẹ̀ yín yóò fi yín hàn.

Numbers 32:23 in English

Numbers 32:23 · Berean Standard Bible

But if you do not do this, you will certainly sin against the LORD—and be assured that your sin will find you out.

Context

21Bí gbogbo yín yóò bá lọ sí Jordani ní ìhámọ́ra níwájú Olúwa, títí yóò fi lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ kúrò níwájú rẹ̀. 22Tí a ó sì fi ṣe ilẹ̀ náà níwájú Olúwa; ẹ̀yin lè padà tí yóò sì di òmìnira lọ́wọ́ ìdè níwájú Olúwa àti Israẹli. Ilẹ̀ yìí yóò sì jẹ́ tiyín níwájú Olúwa. 23“Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kọ̀ láti ṣe èyí, ẹ̀yin yóò máa dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa; kí ẹ̀yin kí ó sì mọ̀ dájú pé ẹ̀ṣẹ̀ yín yóò fi yín hàn. 24Ẹ kọ́ ilé fún àwọn obìnrin yín àti ọmọ wẹ́wẹ́ yín, àti ilé fún agbo ẹran yín, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó ṣe ohun tí ẹ ti pinnu.” 25Àwọn ọmọ Gadi àti ọmọ Reubeni sọ fún Mose pé, “Àwa ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí olúwa wa ti pàṣẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.