Native Bible

Numbers 31:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yan nínú àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn Israẹli, ẹgbẹ̀rún (1,000) ènìyàn láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ènìyàn tí ó wọ ìhámọ́ra ogun.

Numbers 31:5 in English

Numbers 31:5 · Berean Standard Bible

So a thousand men were recruited from each tribe of Israel—twelve thousand armed for war.

Context

3Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ wọ ogun fún àwọn kan nínú yín láti lọ da ojú ìjà kọ àwọn ọmọ Midiani láti gba ẹ̀san Olúwa lára wọn. 4Rán ẹgbẹ̀rún (1,000) ọmọ-ogun láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní Israẹli.” 5Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì yan nínú àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn Israẹli, ẹgbẹ̀rún (1,000) ènìyàn láti inú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ènìyàn tí ó wọ ìhámọ́ra ogun. 6Mose rán wọn lọ sí ogun, ẹgbẹ̀rún (1,000) láti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú Finehasi ọmọ Eleasari, ti ó jẹ́ àlùfáà, ti òun ti ohun èlò ibi mímọ́ àti ìpè wọ̀n-ọn-nì ní ọwọ́ rẹ̀. 7Wọ́n dojú ìjà kọ Midiani gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, kí wọn sì pa gbogbo wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.