Native Bible

Numbers 3:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí, Nadabu ni àkọ́bí, Abihu, Eleasari àti Itamari.

Numbers 3:2 in English

Numbers 3:2 · Berean Standard Bible

These are the names of the sons of Aaron: Nadab the firstborn, then Abihu, Eleazar, and Ithamar.

Context

1Ìwọ̀nyí ni ìdílé Aaroni àti Mose ní ìgbà tí Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai. 2Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni nìwọ̀nyí, Nadabu ni àkọ́bí, Abihu, Eleasari àti Itamari. 3Orúkọ àwọn ọmọ Aaroni ni ìwọ̀nyí, àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn, àwọn tí a fi joyè àlùfáà láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 4Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu ti kú níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n rú iná àjèjì níwájú Olúwa nínú ijù Sinai, àwọn méjèèjì kò sì ní ọmọ. Báyìí Eleasari àti Itamari ló ṣiṣẹ́ àlùfáà nígbà ayé Aaroni baba wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.