Native Bible

Numbers 3:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Israẹli yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni Olúwa.”

Numbers 3:13 in English

Numbers 3:13 · Berean Standard Bible

for all the firstborn are Mine. On the day I struck down every firstborn in the land of Egypt, I consecrated to Myself all the firstborn in Israel, both man and beast. They are Mine; I am the LORD.”

Context

11Olúwa tún sọ fún Mose pé, 12“Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Lefi láàrín àwọn ọmọ Israẹli dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Israẹli. Ti èmi ni àwọn ọmọ Lefi, 13nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ejibiti ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Israẹli yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni Olúwa.” 14Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose ní aginjù Sinai pé, 15“Ka àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn kí o ka gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.