Numeri 28:4
Numbers 28:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.
Numbers 28:4 in English
Numbers 28:4 · Berean Standard Bible
Offer one lamb in the morning and the other at twilight,*
Context
2“Fún àwọn ọmọ Israẹli ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi.’ 3Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa: akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun ní ojoojúmọ́. 4Pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́. 5Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ tí ó jẹ́ ìdámẹ́wàá efa ìyẹ̀fun dáradára tí a pò mọ́ ìdámẹ́rin hínì òróró tí a yọ lára Olifi. 6Èyí ni ẹbọ sísun gbogbo ìgbà tí a fi lélẹ̀ ní òkè Sinai gẹ́gẹ́ bí olóòórùn dídùn ẹbọ tí a fi iná sun fún Olúwa pẹ̀lú iná.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.