Native Bible

Numbers 28:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

Numbers 28:26 in English

Numbers 28:26 · Berean Standard Bible

On the day of firstfruits, when you present an offering of new grain to the LORD during the Feast of Weeks,* you are to hold a sacred assembly; you must not do any regular work.

Context

24Báyìí ní kí ẹ̀yin rúbọ ní ọjọọjọ́, jálẹ̀ ní ọjọ́ méjèèje, oúnjẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí olóòórùn dídùn sí Olúwa; ó rú u pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu. 25Ní ọjọ́ keje kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. 26“ ‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. 27Kí ẹ mú ẹbọ sísun ẹgbọrọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn fún Olúwa. 28Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù ní kí ẹ rú ẹbọ ohun mímu ìdámẹ́ta pẹ̀lú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò pẹ̀lú àgbò kan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.