Numeri 27:22
Numbers 27:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó mú Joṣua ó sì mú kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti níwájú gbogbo ìjọ.
Numbers 27:22 in English
Numbers 27:22 · Berean Standard Bible
Moses did as the LORD had commanded him. He took Joshua, had him stand before Eleazar the priest and the whole congregation,
Context
20Kí ìwọ kí ó sì fi nínú ọláńlá rẹ sí i lára, kí gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kí ó lè gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu. 21Kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà, tí yóò gba ìpinnu fún láti béèrè Urimu níwájú Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí òfin yìí ni òun pẹ̀lú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò jáde lọ, pẹ̀lú òfin rẹ̀ sì ni wọn ó wọlé.” 22Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó mú Joṣua ó sì mú kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti níwájú gbogbo ìjọ. 23Nígbà náà ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, ó sì fi àṣẹ fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.