Native Bible

Numbers 27:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jẹ́ kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti ojú gbogbo àwọn ìjọ ènìyàn Israẹli kí o sì fi àṣẹ fún un ní ojú wọn.

Numbers 27:19 in English

Numbers 27:19 · Berean Standard Bible

Have him stand before Eleazar the priest and the whole congregation, and commission him in their sight.

Context

17láti máa darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.” 18Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkùnrin nínú ẹni tí èmi wà, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e. 19Jẹ́ kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti ojú gbogbo àwọn ìjọ ènìyàn Israẹli kí o sì fi àṣẹ fún un ní ojú wọn. 20Kí ìwọ kí ó sì fi nínú ọláńlá rẹ sí i lára, kí gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kí ó lè gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu. 21Kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà, tí yóò gba ìpinnu fún láti béèrè Urimu níwájú Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí òfin yìí ni òun pẹ̀lú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò jáde lọ, pẹ̀lú òfin rẹ̀ sì ni wọn ó wọlé.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.