Numeri 25:7
Numbers 25:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.
Numbers 25:7 in English
Numbers 25:7 · Berean Standard Bible
On seeing this, Phinehas son of Eleazar, the son of Aaron the priest, got up from the assembly, took a spear in his hand,
Context
5Mose sọ fún àwọn onídàájọ́ Israẹli, “Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ èyí tí ó darapọ̀ ní fífi orí balẹ̀ fún Baali-Peori.” 6Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Israẹli sì mú obìnrin Midiani wá síwájú ojú Mose àti gbogbo ìjọ ti Israẹli wọ́n sì ń sọkún ní àbáwọlé àgọ́ ìpàdé. 7Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. 8Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Israẹli yìí lọ sínú àgọ́. Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Israẹli àti sí ara obìnrin náà. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn lórí àwọn ọmọ Israẹli sì dúró; 9ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn náà jẹ́ ẹgbàá méjìlá (24,000).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.