Native Bible

Numbers 22:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà angẹli Olúwa béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí o fi na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹ́ta yìí? Mo wá síbí láti kọ ojú ìjà sí ọ nítorí ọ̀nà rẹ kò tọ́ níwájú mi.

Numbers 22:32 in English

Numbers 22:32 · Berean Standard Bible

The angel of the LORD asked him, “Why have you beaten your donkey these three times? Behold, I have come out to oppose you, because your way is perverse * before me.

Context

30Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sọ fún Balaamu pé, “Ṣé mi kì í ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni, tí o máa ń gùn ní gbogbo ìgbà, láti ìgbà pípẹ́ wá? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?” “Rárá,” Ó dáhùn. 31Nígbà náà Olúwa ṣí ojú Balaamu, ó sì rí angẹli Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà rẹ̀ tí ó fàyọ. Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba. 32Nígbà náà angẹli Olúwa béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí o fi na kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ nígbà mẹ́ta yìí? Mo wá síbí láti kọ ojú ìjà sí ọ nítorí ọ̀nà rẹ kò tọ́ níwájú mi. 33Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí mi ó sì yà kúrò fún mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta yìí. Tí ó bá jẹ́ wí pé kò yà kúrò. Èmi kì ìbá ti pa ọ́ pátápátá nísinsin yìí, ṣùgbọ́n Èmi yóò sì dá òun sí.” 34Balaamu sọ fún angẹli Olúwa pé, “Mo ti dẹ́ṣẹ̀, èmi kò mọ̀ pé o dúró níwájú ọ̀nà láti dojúkọ mí, nísinsin yìí tí inú rẹ kò bá dùn, èmi ó padà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.