Numeri 22:29
Numbers 22:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Balaamu sọ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pé, “Nítorí ìwọ fi mí ṣẹ̀sín! Bí mo bá ní idà ní ọwọ́ ni èmi ìbá pa ọ́ nísinsin yìí.”
Numbers 22:29 in English
Numbers 22:29 · Berean Standard Bible
Balaam answered the donkey, “You have made a fool of me! If I had a sword in my hand, I would kill you right now!”
Context
27Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí angẹli Olúwa, ó sì jókòó ní abẹ́ Balaamu, inú sì bí i tó sì nà án pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀. 28Nígbà náà Olúwa ṣí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Balaamu pé, “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta?” 29Balaamu sọ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pé, “Nítorí ìwọ fi mí ṣẹ̀sín! Bí mo bá ní idà ní ọwọ́ ni èmi ìbá pa ọ́ nísinsin yìí.” 30Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sọ fún Balaamu pé, “Ṣé mi kì í ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ni, tí o máa ń gùn ní gbogbo ìgbà, láti ìgbà pípẹ́ wá? Ǹjẹ́ mo hu irú ìwà báyìí sí ọ rí?”
“Rárá,” Ó dáhùn. 31Nígbà náà Olúwa ṣí ojú Balaamu, ó sì rí angẹli Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà rẹ̀ tí ó fàyọ. Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.