Native Bible

Numbers 21:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.”

Numbers 21:8 in English

Numbers 21:8 · Berean Standard Bible

Then the LORD said to Moses, “Make a fiery serpent and mount it on a pole. When anyone who is bitten looks at it, he will live.”

Context

6Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú. 7Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mose wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí asọ̀rọ̀-òdì sí Olúwa àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí Olúwa mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mose gbàdúrà fún àwọn ènìyàn. 8Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.” 9Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè. 10Àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú wọ́n sì péjọ sí Obotu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.