Numeri 2:24
Numbers 2:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Efraimu, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta.
Numbers 2:24 in English
Numbers 2:24 · Berean Standard Bible
The total number of men in the divisions of the camp of Ephraim is 108,100; they shall set out third.
Context
22Ẹ̀yà Benjamini ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni. 23Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje (35,400). 24Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Efraimu, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta. 25Ní ìhà àríwá:
ni ìpín Dani yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Dani ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. 26Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (62,700).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.