Numeri 2:18
Numbers 2:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ìhà ìlà-oòrùn: ni ìpín Efraimu yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀. Olórí Efraimu ni Eliṣama ọmọ Ammihudu.
Numbers 2:18 in English
Numbers 2:18 · Berean Standard Bible
On the west side, the divisions of Ephraim are to camp under their standard: The leader of the Ephraimites is Elishama son of Ammihud,
Context
16Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Reubeni, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rin ó lé àádọ́talélégbèje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì. 17Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi àti àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀síwájú láàrín ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láààyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀. 18Ní ìhà ìlà-oòrùn:
ni ìpín Efraimu yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀. Olórí Efraimu ni Eliṣama ọmọ Ammihudu. 19Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì lé ó lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500). 20Ẹ̀yà Manase ni yóò tẹ̀lé wọn. Olórí Manase ni Gamalieli ọmọ Pedasuri.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.