Numeri 18:23
Numbers 18:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọ Lefi ní ó gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí wọ́n bá kúrò láti ṣe é. Èyí ni ìlànà láéláé fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Wọn kò nígbà ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli.
Numbers 18:23 in English
Numbers 18:23 · Berean Standard Bible
The Levites are to perform the work of the Tent of Meeting, and they must bear their iniquity. This is a permanent statute for the generations to come. The Levites will not receive an inheritance among the Israelites.
Context
21“Mó ti fún àwọn ọmọ Lefi ní gbogbo ìdámẹ́wàá ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi àgọ́ ìpàdé. 22Láti ìsinsin yìí àwọn ọmọ Israẹli, kò gbọdọ̀ súnmọ́ àgọ́ ìpàdé, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò jẹ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn á sì kú. 23Àwọn ọmọ Lefi ní ó gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ tí ó wà nínú àgọ́ ìpàdé, wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí wọ́n bá kúrò láti ṣe é. Èyí ni ìlànà láéláé fún àwọn ìran tí ó ń bọ̀. Wọn kò nígbà ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli. 24Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fún àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí ogún wọn, ìdákan nínú ìdámẹ́wàá tí àwọn ọmọ Israẹli pèsè gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa. Èyí ni mo wí nípa wọn. Wọn kò ní gba ogún kankan láàrín àwọn ọmọ Israẹli.” 25Olúwa sọ fún Mose pé,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.