Native Bible

Numbers 18:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo àkọ́so nǹkan ilẹ̀ wọ́n tí wọn mú wá fún Olúwa yóò jẹ́ tìrẹ. Ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ, àwọn tí ó jẹ́ mímọ́ nínú ìdílé rẹ lè jẹ ẹ́.

Numbers 18:13 in English

Numbers 18:13 · Berean Standard Bible

The firstfruits of everything in their land that they bring to the LORD will belong to you. Every ceremonially clean person in your household may eat them.

Context

11“Èyí tún jẹ́ tìrẹ pẹ̀lú: ohunkóhun tí a bá yà sọ́tọ̀ lára ẹ̀bùn ọrẹ fífì àwọn ọmọ Israẹli. Mó fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìpín tí yóò máa ṣe déédé nínú ìdílé rẹ, tí o bá wà ní mímọ́ ni o le jẹ ẹ́. 12“Mo fún ọ ní gbogbo òróró tí ó dára jùlọ àti gbogbo ọtí tuntun dáradára jùlọ àti ọkà tí wọ́n mú wá fún Olúwa ní àkọ́so ohun ọ̀gbìn wọn tí wọ́n kórè. 13Gbogbo àkọ́so nǹkan ilẹ̀ wọ́n tí wọn mú wá fún Olúwa yóò jẹ́ tìrẹ. Ẹnikẹ́ni nínú ìdílé rẹ, àwọn tí ó jẹ́ mímọ́ nínú ìdílé rẹ lè jẹ ẹ́. 14“Gbogbo nǹkan tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa ní Israẹli jẹ́ tìrẹ. 15Gbogbo àkọ́bí nínú gbogbo ohun alààyè tí wọ́n mú wá fún Olúwa, ìbá à jẹ́ ti ènìyàn tàbí ti ẹranko jẹ́ tìrẹ ṣùgbọ́n o gbọdọ̀ ra gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin padà àti àkọ́bí àwọn ẹranko aláìmọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.