Numeri 16:27
Numbers 16:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ènìyàn sì sún kúrò ní àgọ́ Kora, Datani àti Abiramu. Datani àti Abiramu jáde, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ wọn.
Numbers 16:27 in English
Numbers 16:27 · Berean Standard Bible
So they moved away from the dwellings of Korah, Dathan, and Abiram. Meanwhile, Dathan and Abiram had come out and stood at the entrances to their tents with their wives and children and infants.
Context
25Mose sì dìde lọ bá Datani àti Abiramu àwọn àgbàgbà Israẹli sì tẹ̀lé. 26Ó sì kìlọ̀ fún ìjọ ènìyàn pé, “Ẹ kúrò ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú yìí! Ẹ má ṣe fọwọ́ kan ohun kan tí í ṣe tiwọn kí ẹ má ba à parun nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” 27Àwọn ènìyàn sì sún kúrò ní àgọ́ Kora, Datani àti Abiramu. Datani àti Abiramu jáde, àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọ wọn sì dúró sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ wọn. 28Nígbà náà ni Mose wí pé, “Báyìí ni ẹ ó ṣe mọ̀ pé Olúwa ló rán mi láti ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí àti pé kì í ṣe ìfẹ́ inú mi ni àwọn ohun tí mò ń ṣe. 29Bí àwọn ènìyàn yìí bá kú bí gbogbo ènìyàn ti ń kú, bí ìrírí wọn kò bá sì yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn yòókù, a jẹ́ pé kì í ṣe Olúwa ló rán mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.