Numeri 16:15
Numbers 16:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún Olúwa pé, “Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára!”
Numbers 16:15 in English
Numbers 16:15 · Berean Standard Bible
Then Moses became very angry and said to the LORD, “Do not regard their offering. I have not taken one donkey from them or mistreated a single one of them.”
Context
13Kò ha tó gẹ́ẹ́ pé o ti mú wa jáde láti ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin láti pa wá sínú aginjù yìí? O tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di olúwa lé wa lórí bí? 14Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò sì tí ì mú wa dé ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì pín ilẹ̀ ìní àti ọgbà àjàrà. Ìwọ ha fẹ́ sọ wá di ẹrú bí? Rárá o, àwa kì yóò gòkè wá!” 15Nígbà náà ni Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún Olúwa pé, “Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára!” 16Mose sọ fún Kora pé, “Ìwọ àti ọmọ lẹ́yìn rẹ gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú Olúwa lọ́la—gbogbo yín, ìwọ, àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ àti Aaroni. 17Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín mú àwo tùràrí, kí ó sì fi tùràrí sínú rẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta lé nígba (250) àwo tùràrí kí ẹ sì ko wá síwájú Olúwa. Ìwọ àti Aaroni yóò mú àwo tùràrí wá pẹ̀lú.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.