Native Bible

Numbers 15:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wajawaja yìí ni ẹ sì máa wọ̀ láti lè mú yín rántí gbogbo òfin Olúwa, kí ẹ bá à lè ṣe wọ́n, kí ẹ sì má bá à ṣe àgbèrè nípa títẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àti ojú yín.

Numbers 15:39 in English

Numbers 15:39 · Berean Standard Bible

These will serve as tassels for you to look at, so that you may remember all the commandments of the LORD, that you may obey them and not prostitute yourselves by following your own heart and your own eyes.

Context

37Olúwa sọ fún Mose pé, 38“Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, kí o sọ fún wọn pé: ‘Títí dé àwọn ìran tó ń bọ̀ ni kí wọn máa ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn, kí wọn sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ búlúù sí wajawaja kọ̀ọ̀kan. 39Wajawaja yìí ni ẹ sì máa wọ̀ láti lè mú yín rántí gbogbo òfin Olúwa, kí ẹ bá à lè ṣe wọ́n, kí ẹ sì má bá à ṣe àgbèrè nípa títẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àti ojú yín. 40Nígbà náà ni ẹ ó gbọ́rọ̀ láti pa gbogbo òfin mi mọ́, ẹ ó sì jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run yín. 41Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti Ejibiti láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.