Native Bible

Numbers 15:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣá igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Aaroni àti síwájú gbogbo ìjọ ènìyàn,

Numbers 15:33 in English

Numbers 15:33 · Berean Standard Bible

Those who found the man gathering wood brought him to Moses, Aaron, and the whole congregation,

Context

31Nítorí pé ẹni náà ti kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa ó sì ti rú òfin rẹ̀, a gbọdọ̀ gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí rẹ̀.’ ” 32Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli wà nínú aginjù, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣá igi ní ọjọ́ Ìsinmi. 33Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣá igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Aaroni àti síwájú gbogbo ìjọ ènìyàn, 34wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn. 35Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Kíkú ni ọkùnrin náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sọ ọ́ lókùúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.