Native Bible

Numbers 14:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli pé, “Ilẹ̀ tí a là kọjá láti yẹ̀ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

Numbers 14:7 in English

Numbers 14:7 · Berean Standard Bible

and said to the whole congregation of Israel, “The land we passed through and explored is an exceedingly good land.

Context

5Nígbà náà ni Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli. 6Joṣua ọmọ Nuni àti Kalebu ọmọ Jefunne, tí wọ́n wà lára àwọn to lọ yẹ ilẹ̀ wò sì fa aṣọ wọn ya. 7Wọ́n sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli pé, “Ilẹ̀ tí a là kọjá láti yẹ̀ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọ́pọ̀. 8Bí inú Olúwa bá dùn sí wa, yóò mú wa dé ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tó ń sàn fún wàrà àti fún oyin, yóò fún wa ní ilẹ̀ náà. 9Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú àwa, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.