Native Bible

Numbers 14:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nínú aginjù yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà.

Numbers 14:29 in English

Numbers 14:29 · Berean Standard Bible

Your bodies will fall in this wilderness—all who were numbered in the census, everyone twenty years of age or older—because you have grumbled against Me.

Context

27“Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ìjọ ènìyàn búburú yìí yóò fi máa kùn sí mi? Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi. 28Sọ fún wọn, bí mo ti wà láààyè nítòótọ́ ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín. 29Nínú aginjù yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà. 30Ọ̀kan nínú yín kò ní í dé ilẹ̀ tí mo búra nípa ìgbọ́wọ́sókè láti fi ṣe ibùgbé yín, bí kò ṣe Kalebu ọmọ Jefunne àti Joṣua ọmọ Nuni. 31Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ yín tí ẹ wí pé wọn ó di ìjẹ, àwọn ni n ó mú dé bẹ̀ láti gbádùn ilẹ̀ tí ẹ kọ̀sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.