Numeri 14:19
Numbers 14:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jì wọ́n, mo bẹ̀ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ, bí o ti ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n láti ìgbà tí o ti kó wọn kúrò ní Ejibiti di ìsin yìí.”
Numbers 14:19 in English
Numbers 14:19 · Berean Standard Bible
Pardon, I pray, the iniquity of this people, in keeping with the greatness of Your loving devotion, just as You have forgiven them ever since they left Egypt.”
Context
17“Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ pé, 18‘Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró ṣinṣin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jì. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’ 19Dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jì wọ́n, mo bẹ̀ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ, bí o ti ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n láti ìgbà tí o ti kó wọn kúrò ní Ejibiti di ìsin yìí.” 20Olúwa sì dáhùn pé, “Mo ti dáríjì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. 21Ṣùgbọ́n nítòótọ́ bí mo ti wà láààyè, gbogbo ayé yóò kún fún ògo Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.