Numeri 13:27
Numbers 13:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí, “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí.
Numbers 13:27 in English
Numbers 13:27 · Berean Standard Bible
And they gave this account to Moses: “We went into the land to which you sent us, and indeed, it is flowing with milk and honey. Here is some of its fruit!
Context
25Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. 26Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí, “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí. 28Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀. A tilẹ̀ rí àwọn irú-ọmọ Anaki níbẹ̀. 29Àwọn Amaleki ń gbé ní ìhà gúúsù; àwọn ará Hiti, àwọn ará Jebusi àti àwọn ará Amori ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ẹ̀bá òkun àti ní etí bèbè Jordani.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.