Numeri 11:6
Numbers 11:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n báyìí gbogbo ara wa ti gbẹ, kò sí ohun mìíràn láti jẹ àfi manna nìkan tí a rí yìí!”
Numbers 11:6 in English
Numbers 11:6 · Berean Standard Bible
But now our appetite is gone; there is nothing to see but this manna!”
Context
4Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrín àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn fi ìtara béèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Israẹli náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún wí pé, “Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí! 5Àwa rántí ẹja tí à ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ ní Ejibiti, apálà, bàrà, ewébẹ̀, àlùbọ́sà àti àwọn ẹ̀fọ́ mìíràn. 6Ṣùgbọ́n báyìí gbogbo ara wa ti gbẹ, kò sí ohun mìíràn láti jẹ àfi manna nìkan tí a rí yìí!” 7Manna náà dàbí èso korianderi, ìrísí rẹ̀ sì dàbí oje igi. 8Àwọn ènìyàn náà ń lọ káàkiri láti kó o, wọn ó lọ̀ ọ́ lórí ọlọ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n le sè é nínú ìkòkò tàbí kí wọn ó fi ṣe àkàrà, adùn rẹ̀ yóò sì dàbí adùn ohun tí a fi òróró ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.