Numeri 10:8
Numbers 10:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè. Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀.
Numbers 10:8 in English
Numbers 10:8 · Berean Standard Bible
The sons of Aaron, the priests, are to sound the trumpets. This shall be a permanent statute for you and the generations to come.
Context
6Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra. Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ àmì fún gbígbéra. 7Nígbà tí o bá fẹ́ pe ìjọ ènìyàn jọ, fun fèrè nìkan, má ṣe fun ti ìdágìrì pẹ̀lú rẹ̀. 8“Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè. Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀. 9Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀tá tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì rántí yín níwájú Olúwa, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. 10Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.