Numeri 1:20
Numbers 1:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Láti ìran Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Israẹli, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
Numbers 1:20 in English
Numbers 1:20 · Berean Standard Bible
From the sons of Reuben, the firstborn of Israel, according to the records of their clans and families, counting one by one the names of every male twenty years of age or older who could serve in the army,
Context
18wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Israẹli jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè, 19gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú aginjù Sinai. 20Láti ìran Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Israẹli, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn. 21Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Reubeni jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500). 22Láti ìran Simeoni, gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.