Native Bible

Numbers 1:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.

Numbers 1:2 in English

Numbers 1:2 · Berean Standard Bible

“Take a census of the whole congregation of Israel by their clans and families, listing every man by name, one by one.

Context

1Olúwa bá Mose sọ̀rọ̀ ní aginjù Sinai nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ó wí pé, 2“Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Israẹli nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. 3Ìwọ àti Aaroni ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun. 4Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan láti inú olúkúlùkù ẹ̀yà kí ó sì wá pẹ̀lú yín, kí olúkúlùkù jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.