Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà ni Jeṣua, àti Bani, Kadmieli, Ṣebaniah, Bunni, Ṣerebiah, Bani àti Kenaani gòkè dúró lórí àwọn àtẹ̀gùn àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì fi ohùn rara kígbe sí Olúwa Ọlọ́run wọn.

Nehemiah 9:4 in English

Nehemiah 9:4 · Berean Standard Bible

And the Levites—Jeshua, Bani, Kadmiel, Shebaniah, Bunni, Sherebiah, Bani, and Chenani—stood on the raised platform and cried out in a loud voice to the LORD their God.

Context

2Àwọn ọkùnrin Israẹli sì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú gbogbo àwọn àjèjì. Wọ́n dúró ní ààyè e wọn, wọ́n sì ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ wọn àti iṣẹ́ búburú àwọn baba wọn. 3Wọ́n dúró sí ibi tí wọ́n wà, wọ́n sì fi ìdámẹ́rin ọjọ́ kà nínú ìwé òfin Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì tún fi ìdámẹ́rin mìíràn ní ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ní sí sin Olúwa Ọlọ́run wọn. 4Nígbà náà ni Jeṣua, àti Bani, Kadmieli, Ṣebaniah, Bunni, Ṣerebiah, Bani àti Kenaani gòkè dúró lórí àwọn àtẹ̀gùn àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì fi ohùn rara kígbe sí Olúwa Ọlọ́run wọn. 5Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi: Jeṣua, Kadmieli, Bani, Haṣbneiah, Ṣerebiah, Hodiah, Ṣebaniah àti Petahiah—wí pé, “Ẹ dìde ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó wà láé àti láéláé.” “Ìbùkún ni fún orúkọ rẹ tí ó ní ògo, kí ó sì di gbígbéga ju gbogbo ìbùkún àti ìyìn lọ. 6Ìwọ nìkan ni Olúwa. Ìwọ ni ó dá ọ̀run, àní àwọn ọ̀run tí ó ga jù pẹ̀lú gbogbo ogun wọn, ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ìwọ sì pa gbogbo wọn mọ́ láàyè, ogun ọ̀run sì ń sìn ọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.