Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nehemiah wí pé, “Ẹ lọ kí ẹ gbádùn oúnjẹ tí ẹ yàn láàyò kí ẹ sì mú ohun dídùn, kí ẹ sì mú díẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn tí kò ní. Ọjọ́ yìí, mímọ́ ni fún Olúwa wa. Ẹ má ṣe banújẹ́, nítorí ayọ̀ Olúwa ni agbára yín.”

Nehemiah 8:10 in English

Nehemiah 8:10 · Berean Standard Bible

Then Nehemiah told them, “Go and eat what is rich, drink what is sweet, and send out portions to those who have nothing prepared, since today is holy to our Lord. Do not grieve, for the joy of the LORD is your strength.”

Context

8Wọ́n kà láti inú ìwé òfin Ọlọ́run, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àlàyé kí ohun tí wọ́n kà bá à le yé àwọn ènìyàn yékéyéké. 9Nígbà náà ni Nehemiah tí ó jẹ́ baálẹ̀, Esra àlùfáà àti akọ̀wé, àti àwọn Lefi tí wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn wí fún gbogbo wọn pé, “Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ má ṣe ṣọ̀fọ̀ tàbí sọkún,” nítorí gbogbo àwọn ènìyàn ti ń sọkún bí wọ́n ti ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ inú òfin náà. 10Nehemiah wí pé, “Ẹ lọ kí ẹ gbádùn oúnjẹ tí ẹ yàn láàyò kí ẹ sì mú ohun dídùn, kí ẹ sì mú díẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn tí kò ní. Ọjọ́ yìí, mímọ́ ni fún Olúwa wa. Ẹ má ṣe banújẹ́, nítorí ayọ̀ Olúwa ni agbára yín.” 11Àwọn ọmọ Lefi mú kí gbogbo ènìyàn dákẹ́ jẹ́, wọ́n wí pé, “Ẹ dákẹ́, nítorí mímọ́ ni ọjọ́ yìí. Ẹ má ṣe banújẹ́.” 12Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn lọ láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì fi ìpín oúnjẹ ránṣẹ́, wọ́n sì ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ ńlá, nítorí báyìí àwọn òfin tí a sọ di mímọ́ fun wọn ti yé wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.