Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gbogbo wọn múra láti dẹ́rùbà wá, wọ́n ń rò ó wí pé, “Ọwọ́ wọn kò ní ran iṣẹ́ náà, àti wí pé wọn kò ní parí rẹ̀.” Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà pé, “Nísinsin yìí Ọlọ́run fi agbára fún ọwọ́ mi.”

Nehemiah 6:9 in English

Nehemiah 6:9 · Berean Standard Bible

For they were all trying to frighten us, saying, “Their hands will be weakened in the work, and it will never be finished.” But now, my God,* strengthen my hands.

Context

7àti pé ó ti yan àwọn wòlíì kí wọn lè kéde nípa rẹ̀ ní Jerusalẹmu: ‘Ọba kan wà ní Juda!’ Nísinsin yìí, ìròyìn yìí yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọba; nítorí náà wá, jẹ́ kí a bá ara wa sọ̀rọ̀.” 8Mo dá èsì yìí padà sí i pé, “Kò sí ohun kan nínú irú ohun tí ìwọ sọ tí ó ṣẹlẹ̀; ìwọ kàn rò wọ́n ní orí ara rẹ ni.” 9Gbogbo wọn múra láti dẹ́rùbà wá, wọ́n ń rò ó wí pé, “Ọwọ́ wọn kò ní ran iṣẹ́ náà, àti wí pé wọn kò ní parí rẹ̀.” Ṣùgbọ́n mo gbàdúrà pé, “Nísinsin yìí Ọlọ́run fi agbára fún ọwọ́ mi.” 10Ní ọjọ́ kan mo lọ sí ilé Ṣemaiah ọmọ Delaiah, ọmọ Mehetabeeli, ẹni tí a há mọ́ sínú ilé rẹ̀. Ó wí pé, “Jẹ́ kí a pàdé ní ilé Ọlọ́run nínú tẹmpili, kí o sì jẹ́ kí a pa àwọn ìlẹ̀kùn tẹmpili dé, nítorí àwọn ènìyàn ń bọ̀ láti pa ọ́, ní òru ni wọn yóò wá láti pa ọ́.” 11Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí irú ènìyàn bí èmi sálọ? Tàbí kí ènìyàn bí èmi sálọ sínú tẹmpili láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là? Èmi kò ní lọ!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.