Nehemiah 6:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Sanballati, Tobiah Geṣemu ará Arabia àti àwọn ọ̀tá wa tókù gbọ́ pé, mo ti tún odi náà mọ, kò sì sí àlàfo kankan tí ó ṣẹ́kù nínú rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ì tí ì ri àwọn ìlẹ̀kùn ibodè ní àkókò náà.
Nehemiah 6:1 in English
Nehemiah 6:1 · Berean Standard Bible
When Sanballat, Tobiah, Geshem the Arab, and the rest of our enemies heard that I had rebuilt the wall and not a gap was left—though to that time I had not yet installed the doors in the gates—
Context
1Nígbà tí Sanballati, Tobiah Geṣemu ará Arabia àti àwọn ọ̀tá wa tókù gbọ́ pé, mo ti tún odi náà mọ, kò sì sí àlàfo kankan tí ó ṣẹ́kù nínú rẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò ì tí ì ri àwọn ìlẹ̀kùn ibodè ní àkókò náà. 2Sanballati àti Geṣemu rán iṣẹ́ yìí sí mi pé, “Wá jẹ́ kí a jọ pàdé pọ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìletò ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ono.”
Ṣùgbọ́n wọ́n ń gbèrò láti ṣe mí ní ibi; 3bẹ́ẹ̀ ni mo rán oníṣẹ́ padà pẹ̀lú èsì yìí pé, “Èmi ń ṣe iṣẹ́ ńlá kan, èmi kò le è sọ̀kalẹ̀ wá. Èéṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró, nígbà tí mo bá fi í sílẹ̀ tí mo sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.